Native Bible

Joshua 7:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí,

Joshua 7:20 in English

Joshua 7:20 · Berean Standard Bible

“It is true,” Achan replied, “I have sinned against the LORD, the God of Israel. This is what I did:

Context

18Joṣua sì mú ìdílé Simri wá síwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ti ẹ̀yà Juda. 19Nígbà náà ní Joṣua sọ fún Akani pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, kí o sì fi ìyìn fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.” 20Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí, 21nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.” 22Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì sáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.