Joṣua 4:12
Joshua 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.
Joshua 4:12 in English
Joshua 4:12 · Berean Standard Bible
The Reubenites, the Gadites, and the half-tribe of Manasseh crossed over before the Israelites, armed for battle as Moses had instructed them.
Context
10Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá, 11bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdìkejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n. 12Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn. 13Àwọn bí ọ̀kẹ́ méjì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko láti jagun. 14Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.