Native Bible

Joshua 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,

Joshua 4:10 in English

Joshua 4:10 · Berean Standard Bible

Now the priests who carried the ark remained standing in the middle of the Jordan until the people had completed everything the LORD had commanded Joshua to tell them, just as Moses had directed Joshua. The people hurried across,

Context

8Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀. 9Joṣua sì to òkúta méjìlá náà sí àárín odò Jordani fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí. 10Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá, 11bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdìkejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n. 12Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.