Joṣua 24:30
Joshua 24:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi.
Joshua 24:30 in English
Joshua 24:30 · Berean Standard Bible
And they buried him in the land of his inheritance, at Timnath-serah * in the hill country of Ephraim, north of Mount Gaash.
Context
28Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. 29Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún. 30Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. 31Israẹli sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli. 32Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́rùn-ún fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.