Native Bible

Joshua 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”

Joshua 22:5 in English

Joshua 22:5 · Berean Standard Bible

But be very careful to observe the commandment and the law that Moses the servant of the LORD gave you: to love the LORD your God, to walk in all His ways, to keep His commandments, to hold fast to Him, and to serve Him with all your heart and with all your soul.”

Context

3Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́. 4Nísinsin yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdìkejì Jordani. 5Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.” 6Nígbà náà ni Joṣua súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn. 7(Mose ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani, Joṣua sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yòókù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jordani, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Joṣua súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.