Joṣua 22:21
Joshua 22:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Reubeni, Gadi àti ẹ̀yà Manase sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Israẹli pé.
Joshua 22:21 in English
Joshua 22:21 · Berean Standard Bible
Then the Reubenites, the Gadites, and the half-tribe of Manasseh answered the leaders of the clans of Israel:
Context
19Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa. 20Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ” 21Nígbà náà ni Reubeni, Gadi àti ẹ̀yà Manase sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Israẹli pé. 22Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀, jẹ́ kí Israẹli pẹ̀lú kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìṣọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe gbà wa ní òní yìí. 23Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.