Native Bible

Joshua 22:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.

Joshua 22:12 in English

Joshua 22:12 · Berean Standard Bible

And when they heard this, the whole congregation of Israel assembled at Shiloh to go to war against them.

Context

10Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. 11Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli, 12gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun. 13Àwọn ọmọ Israẹli rán Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà, sí ilẹ̀ Gileadi, sí Reubeni, sí Gadi àti sí ìdajì ẹ̀yà Manase. 14Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.