Native Bible

Joshua 21:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni Olúwa fún Israẹli ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

Joshua 21:43 in English

Joshua 21:43 · Berean Standard Bible

Thus the LORD gave Israel all the land He had sworn to give their fathers, and they took possession of it and settled in it.

Context

41Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Lefi tó wà láàrín ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ méjìdínláàádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn. 42Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí. 43Báyìí ni Olúwa fún Israẹli ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. 44Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè dojúkọ wọ́n. Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn ní ọwọ́. 45Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí Olúwa ṣe fún ilé Israẹli tí ó kùnà, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.