Native Bible

Joshua 20:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda.

Joshua 20:7 in English

Joshua 20:7 · Berean Standard Bible

So they set apart Kedesh in Galilee in the hill country of Naphtali, Shechem in the hill country of Ephraim, and Kiriath-arba (that is, Hebron) in the hill country of Judah.

Context

5Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ láìmọ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 6Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.” 7Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda. 8Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase. 9Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé ní àárín wọn tí ó ṣèèṣì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.