Joṣua 2:21
Joshua 2:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.” Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.
Joshua 2:21 in English
Joshua 2:21 · Berean Standard Bible
“Let it be as you say,” she replied, and she sent them away. And when they had gone, she tied the scarlet cord in the window.
Context
19Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án. 20Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.” 21Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.”
Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé. 22Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn. 23Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà. Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.