Joṣua 2:19
Joshua 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án.
Joshua 2:19 in English
Joshua 2:19 · Berean Standard Bible
If anyone goes out the door of your house into the street, his blood will be on his own head, and we will be innocent. But if a hand is laid on anyone with you in the house, his blood will be on our heads.
Context
17Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí. 18Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ. 19Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án. 20Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.” 21Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.”
Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.