Native Bible

Joshua 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Saridi sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tabori, ó sì lọ sí Daberati, ó sì gòkè lọ sí Jafia.

Joshua 19:12 in English

Joshua 19:12 · Berean Standard Bible

From Sarid it turned eastward along the border of Chisloth-tabor and went on to Daberath and up to Japhia.

Context

10Kèké kẹta jáde fún Sebuluni, ní agbo ilé ní agbo ilé ààlà ìní wọn sì lọ títí dé Saridi. 11Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Marala, ó sì dé Dabbeṣeti, ó sì lọ títí dé odo ní ẹ̀bá Jokneamu. 12Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Saridi sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tabori, ó sì lọ sí Daberati, ó sì gòkè lọ sí Jafia. 13Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Heferi àti Eti-Kaṣini, ó sì jáde ní Rimoni, ó sì yí sí ìhà Nea. 14Ní ibẹ̀, ààlà sì yíká ní ìhà àríwá lọ sí Hnatoni ó sì pín ní àfonífojì Ifita-Eli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.