Joṣua 18:8
Joshua 18:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.”
Joshua 18:8 in English
Joshua 18:8 · Berean Standard Bible
As the men got up to go out, Joshua commanded them to map out the land, saying, “Go and survey the land, map it out, and return to me. Then I will cast lots for you here in Shiloh in the presence of the LORD.”
Context
6Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. 7Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.” 8Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.” 9Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo. 10Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.