Native Bible

Joshua 18:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”

Joshua 18:7 in English

Joshua 18:7 · Berean Standard Bible

The Levites, however, have no portion among you, because their inheritance is the priesthood of the LORD. And Gad, Reuben, and half the tribe of Manasseh have already received the inheritance that Moses the servant of the LORD gave them beyond the Jordan to the east.”

Context

5Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. 6Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. 7Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.” 8Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.” 9Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.