Joṣua 18:20
Joshua 18:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn.
Joshua 18:20 in English
Joshua 18:20 · Berean Standard Bible
On the east side the border was the Jordan. These were the borders around the inheritance of the clans of the tribe of Benjamin.
Context
18Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. 19Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù. 20Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.
Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn. 21Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:
Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi, 22Beti-Araba, Semaraimu, Beteli,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.