Native Bible

Joshua 17:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Efraimu bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì ṣán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Peresi àti ará Refaimu.”

Joshua 17:15 in English

Joshua 17:15 · Berean Standard Bible

Joshua answered them, “If you have so many people that the hill country of Ephraim is too small for you, go to the forest and clear for yourself an area in the land of the Perizzites and the Rephaim.”

Context

13Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kenaani sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátápátá. 14Àwọn ọmọ Josẹfu sì wí fún Joṣua pé, “Èéṣe tí ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdákan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọ́pọ̀.” 15Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Efraimu bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì ṣán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Peresi àti ará Refaimu.” 16Àwọn ènìyàn Josẹfu dáhùn pé, “Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kenaani tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Beti-Ṣeani àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní àfonífojì Jesreeli ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.” 17Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ilé Josẹfu: fún Efraimu àti Manase pé, “Lóòtítọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára. Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.