Joṣua 15:12
Joshua 15:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.
Joshua 15:12 in English
Joshua 15:12 · Berean Standard Bible
And the western border was the coastline of the Great Sea. These are the boundaries around the clans of the descendants of Judah.
Context
10Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna. 11Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun. 12Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá.
Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn. 13Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.) 14Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.