Native Bible

Joshua 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mose.

Joshua 14:2 in English

Joshua 14:2 · Berean Standard Bible

Their inheritance was assigned by lot for the nine and a half tribes, as the LORD had commanded through Moses.

Context

1Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kenaani, tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Israẹli pín fún wọn. 2Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mose. 3Mose ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi ni kò fi ìní fún ní àárín àwọn tí ó kù. 4Àwọn ọmọ Josẹfu sì di ẹ̀yà méjì, Manase àti Efraimu. Àwọn ọmọ Lefi kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.