Joṣua 14:13
Joshua 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní.
Joshua 14:13 in English
Joshua 14:13 · Berean Standard Bible
Then Joshua blessed Caleb son of Jephunneh and gave him Hebron as his inheritance.
Context
11Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà. 12Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.” 13Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní. 14Bẹ́ẹ̀ ni Hebroni jẹ́ ti Kalebu ọmọ Jefunne ará Kenissiti láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tọkàntọkàn. 15(Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.)
Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.