Joṣua 10:28
Joshua 10:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko.
Joshua 10:28 in English
Joshua 10:28 · Berean Standard Bible
On that day Joshua captured Makkedah and put it to the sword, along with its king. He devoted to destruction everyone in the city, leaving no survivors. So he did to the king of Makkedah as he had done to the king of Jericho.
Context
26Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́. 27Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí. 28Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko. 29Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú. 30Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.