Native Bible

Joshua 10:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

Joshua 10:27 in English

Joshua 10:27 · Berean Standard Bible

At sunset Joshua ordered that they be taken down from the trees and thrown into the cave in which they had hidden. Then large stones were placed against the mouth of the cave, and the stones are there to this day.

Context

25Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.” 26Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́. 27Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí. 28Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko. 29Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.