Native Bible

Joshua 10:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni.

Joshua 10:23 in English

Joshua 10:23 · Berean Standard Bible

So they brought the five kings out of the cave—the kings of Jerusalem, Hebron, Jarmuth, Lachish, and Eglon.

Context

21Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli. 22Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.” 23Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni. 24Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn. 25Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.