Native Bible

Joshua 10:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.”

Joshua 10:22 in English

Joshua 10:22 · Berean Standard Bible

Then Joshua said, “Open the mouth of the cave and bring those five kings out to me.”

Context

20Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn. 21Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli. 22Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.” 23Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni. 24Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.