Jona 1:14
Jonah 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.”
Jonah 1:14 in English
Jonah 1:14 · Berean Standard Bible
So they cried out to the LORD: “Please, O LORD, do not let us perish on account of this man’s life! Do not charge us with innocent blood! For You, O LORD, have done as You pleased.”
Context
12Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.” 13Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. 14Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” 15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. 16Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.