Jona 1:12
Jonah 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.”
Jonah 1:12 in English
Jonah 1:12 · Berean Standard Bible
“Pick me up,” he answered, “and cast me into the sea, so it may quiet down for you. For I know that I am to blame for this violent storm that has come upon you.”
Context
10Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú Olúwa ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀). 11Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle. 12Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.” 13Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. 14Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.