Joẹli 3:5
Joel 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín.
Joel 3:5 in English
Joel 3:5 · Berean Standard Bible
For you took My silver and gold and carried off My finest treasures to your temples.*
Context
3Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;
wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,
wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu. 4“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn. 7“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.