Native Bible

Job 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

Job 7:3 in English

Job 7:3 · Berean Standard Bible

So I am allotted months of futility, and nights of misery are appointed me.

Context

1“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀? Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe? 2Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji, àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀. 3Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi. 4Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 5Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.