Native Bible

Job 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?

Job 7:17 in English

Job 7:17 · Berean Standard Bible

What is man that You should exalt him, that You should set Your heart upon him,

Context

15Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ. 16O sú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi. 17“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e? 18Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà! 19Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.