Jobu 5:6
Job 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.
Job 5:6 in English
Job 5:6 · Berean Standard Bible
For distress does not spring from the dust, and trouble does not sprout from the ground.
Context
4Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,
a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan. 5Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ,
tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó,
àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì. 6Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,
tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá. 7Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,
gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè. 8“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,
ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.