Native Bible

Job 42:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Job 42:12 in English

Job 42:12 · Berean Standard Bible

So the LORD blessed Job’s latter days more than his first. He owned 14,000 sheep, 6,000 camels, 1,000 yoke of oxen, and 1,000 female donkeys.

Context

10Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí. 11Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a. Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan. 12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 14Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.