Native Bible

Job 37:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.

Job 37:9 in English

Job 37:9 · Berean Standard Bible

The tempest comes from its chamber, and the cold from the driving north winds.

Context

7Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. 8Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn. 9Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká. 10Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì. 11Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.