Jobu 37:5
Job 37:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
Job 37:5 in English
Job 37:5 · Berean Standard Bible
God thunders wondrously with His voice; He does great things we cannot comprehend.
Context
3Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé. 4Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀. 5Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀. 6Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’ 7Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.