Native Bible

Job 35:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

Job 35:7 in English

Job 35:7 · Berean Standard Bible

If you are righteous, what do you give Him, or what does He receive from your hand?

Context

5Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ. 6Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i? 7Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá? 8Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn. 9“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe; wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.