Jobu 32:4
Job 32:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí.
Job 32:4 in English
Job 32:4 · Berean Standard Bible
Now Elihu had waited to speak to Job because the others were older than he.
Context
2Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. 3Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. 4Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. 5Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú. 6Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé,
“Ọmọdé ni èmi,
àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.