Native Bible

Job 30:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.

Job 30:3 in English

Job 30:3 · Berean Standard Bible

Gaunt from poverty and hunger, they gnawed the dry land, and the desolate wasteland by night.

Context

1“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi. 2Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀? 3Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru. 4Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn. 5A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.