Native Bible

Job 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

Job 3:6 in English

Job 3:6 · Berean Standard Bible

If only darkness had taken that night away! May it not appear among the days of the year; may it never be entered in any of the months.

Context

4Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i. 5Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà. 6Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù. 7Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ. 8Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún, tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.