Native Bible

Job 27:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?

Job 27:8 in English

Job 27:8 · Berean Standard Bible

For what is the hope of the godless when he is cut off, when God takes away his life?

Context

6Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi. 7“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo. 8Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde? 9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i? 10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.