Jobu 24:10
Job 24:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà.
Job 24:10 in English
Job 24:10 · Berean Standard Bible
Without clothing, they wander about naked. They carry the sheaves, but still go hungry.
Context
8Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò. 9Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,
wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè. 10Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;
àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà. 11Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn. 12Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.