Jobu 2:8
Job 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.
Job 2:8 in English
Job 2:8 · Berean Standard Bible
And Job took a piece of broken pottery to scrape himself as he sat among the ashes.
Context
6Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” 7Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀. 8Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú. 9Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” 10Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”
Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.