Jobu 15:28
Job 15:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun sì gbé inú ahoro ìlú, àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.
Job 15:28 in English
Job 15:28 · Berean Standard Bible
he will dwell in ruined cities, in abandoned houses destined to become rubble.
Context
26ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,
àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú. 27“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lójú,
o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. 28Òun sì gbé inú ahoro ìlú,
àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé mọ́,
tí ó múra tán láti di àlàpà. 29Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò
lè dúró pẹ́; bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀. 30Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;
ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,
àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.