Native Bible

John 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.

John 8:6 in English

John 8:6 · Berean Standard Bible

They said this to test Him, in order to have a basis for accusing Him. But Jesus bent down and began to write on the ground with His finger.

Context

4Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà. 5Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” 6Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. 7Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” 8Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.