Native Bible

John 8:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili, ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

John 8:20 in English

John 8:20 · Berean Standard Bible

He spoke these words while teaching in the temple courts, near the treasury. Yet no one seized Him, because His hour had not yet come.

Context

18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.” 19Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi, ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 20Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili, ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 21Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.” 22Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.