Johanu 8:19
John 8:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi, ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”
John 8:19 in English
John 8:19 · Berean Standard Bible
“Where is Your Father?” they asked Him. “You do not know Me or My Father,” Jesus answered. “If you knew Me, you would know My Father as well.”
Context
17A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.” 19Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”
Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi, ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 20Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili, ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 21Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.