Native Bible

John 7:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.

John 7:39 in English

John 7:39 · Berean Standard Bible

He was speaking about the Spirit, whom those who believed in Him were later to receive. For the Spirit had not yet been given,* because Jesus had not yet been glorified.

Context

37Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 38Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 39Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo. 40Nítorí náà, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.” 41Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.” Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.