Johanu 7:38
John 7:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”
John 7:38 in English
John 7:38 · Berean Standard Bible
Whoever believes in Me, as the Scripture has said: ‘Streams of living water will flow from within him.’”
Context
36Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ‘Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi,’ àti ‘Ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà’?” 37Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 38Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 39Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo. 40Nítorí náà, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.