Johanu 7:19
John 7:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”
John 7:19 in English
John 7:19 · Berean Standard Bible
Has not Moses given you the law? Yet not one of you keeps it. Why are you trying to kill Me?”
Context
17Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 19Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?” 20Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù, ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” 21Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.