Johanu 7:17
John 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.
John 7:17 in English
John 7:17 · Berean Standard Bible
If anyone desires to do His will, he will know whether My teaching is from God or whether I speak on My own.
Context
15Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?” 16Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. 17Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 19Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.