Native Bible

John 6:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

John 6:7 in English

John 6:7 · Berean Standard Bible

Philip answered, “Two hundred denarii * would not buy enough bread for each of them to have a small piece.”

Context

5Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” 6Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe. 7Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.” 8Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé, 9“Ọmọdékùnrin kan ń bẹ níhìn-ín yìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì, ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.