Native Bible

John 5:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀, ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

John 5:35 in English

John 5:35 · Berean Standard Bible

John was a lamp that burned and gave light, and you were willing for a season to bask in his light.

Context

33“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34Ṣùgbọ́n èmi kò gba ẹ̀rí lọ́dọ̀ ènìyàn, nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀, ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. 36“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ. Nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.