Johanu 5:34
John 5:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi kò gba ẹ̀rí lọ́dọ̀ ènìyàn, nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.
John 5:34 in English
John 5:34 · Berean Standard Bible
Even though I do not accept human testimony, I say these things so that you may be saved.
Context
32Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́. 33“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34Ṣùgbọ́n èmi kò gba ẹ̀rí lọ́dọ̀ ènìyàn, nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀, ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. 36“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ. Nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.